7. Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi.
8. Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai.
9. Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ.
10. Ọlọrun, gẹgẹ bi orukọ rẹ, bẹ̃ni iyìn rẹ de opin aiye: ọwọ ọtún rẹ kún fun ododo.
11. Ki òke Sioni ki o yọ̀, ki inu awọn ọmọbinrin Juda ki o dùn, nitori idajọ rẹ.
12. Rìn Sioni kiri, ki o si yi i ka: kà ile-iṣọ rẹ̀.
13. Kiyesi odi rẹ̀, kiyesi ãfin rẹ̀ wọnni; ki ẹnyin le ma wi fun iran atẹle nyin.
14. Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú.