Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 48:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀.

2. Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla.

3. A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀.

4. Sa wò o, awọn ọba pejọ pọ̀, nwọn jumọ nkọja lọ.

5. Nwọn ri i, bẹ̃li ẹnu yà wọn; a yọ wọn lẹnu, nwọn yara lọ.

6. Ẹ̀ru bà wọn nibẹ, ati irora bi obinrin ti nrọbi.

7. Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi.

8. Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai.

9. Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 48