Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 47:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNYIN enia, gbogbo ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ̀ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun.

2. Nitori Oluwa Ọga-ogo li ẹ̀ru; on li ọba nla lori ilẹ-aiye gbogbo.

3. On ni yio ṣẹ́ awọn enia labẹ wa, ati awọn orilẹ-ède li atẹlẹsẹ wa.

4. On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ.

5. Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè.

6. Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyìn si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn.

7. Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn.

8. Ọlọrun jọba awọn keferi: Ọlọrun joko lori itẹ ìwa-mimọ́ rẹ̀.

9. Awọn alade awọn enia kó ara wọn jọ, ani awọn enia Ọlọrun Abrahamu: nitori asà aiye ti Ọlọrun ni: on li a gbe leke jọjọ.

Ka pipe ipin O. Daf 47