Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 39:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO ni, emi o ma kiyesi ọ̀na mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣẹ̀; emi o fi ijanu ko ara mi li ẹnu nigbati enia buburu ba mbẹ niwaju mi.

2. Mo fi idakẹ yadi, mo tilẹ pa ẹnu mi mọ́ kuro li ọ̀rọ rere: ibinujẹ mi si ru soke.

3. Aiya mi gbona ninu mi, nigbati emi nronu, ina ràn: nigbana ni mo fi ahọn mi sọ̀rọ.

4. Oluwa, jẹ ki emi ki o mọ̀ opin mi ati ìwọn ọjọ mi, bi o ti ri; ki emi ki o le mọ̀ ìgbà ti mo ni nihin.

5. Kiyesi i, iwọ ti sọ ọjọ mi dabi ibu atẹlẹwọ; ọjọ ori mi si dabi asan niwaju rẹ: nitõtọ olukuluku enia ninu ijoko rere rẹ̀ asan ni patapata.

6. Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ.

7. Njẹ nisisiyi, Oluwa kini mo duro de? ireti mi mbẹ li ọdọ rẹ.

8. Gbà mi ninu irekọja mi gbogbo: ki o má si sọ mi di ẹni ẹ̀gan awọn enia buburu.

9. Mo yadi, emi kò ya ẹnu mi; nitoripe iwọ li o ṣe e.

10. Mu ọwọ ìna rẹ kuro li ara mi: emi ṣegbe tan nipa ìja ọwọ rẹ.

11. Nigbati iwọ ba fi ibawi kilọ fun enia nitori ẹ̀ṣẹ, iwọ a ṣe ẹwà rẹ̀ a parun bi kòkoro aṣọ: nitõtọ asan li enia gbogbo.

12. Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri.

13. Da mi si, ki emi li agbara, ki emi ki o to lọ kuro nihinyi, ati ki emi ki o to ṣe alaisi.

Ka pipe ipin O. Daf 39