Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 38:11-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Awọn olufẹ ati awọn ọrẹ mi duro li òkere kuro ni ìna mi, ati awọn ibatan mi duro li òkere rére.

12. Awọn pẹlu ti nwá ọkàn mi dẹkùn silẹ fun mi; ati awọn ti nwá ifarapa mi nsọ̀rọ ohun buburu, nwọn si ngbiro ẹ̀tan li gbogbo ọjọ.

13. Ṣugbọn emi, bi aditi, emi kò gbọ́; ati bi odi ti kò ya ẹnu rẹ̀.

14. Bẹ̃ni mo dabi ọkunrin ti kò gbọ́ran, ati li ẹnu ẹniti iyàn kò si.

15. Nitori, Oluwa, iwọ li emi duro dè, iwọ o gbọ́, Oluwa Ọlọrun mi.

16. Nitori ti mo wipe, Gbohùn mi, ki nwọn ki o má ba yọ̀ mi; nigbati ẹsẹ mi ba yọ́, nwọn o ma gbé ara wọn ga si mi.

17. Emi ti mura ati ṣubu, ikãnu mi si mbẹ nigbagbogbo niwaju mi.

18. Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi.

19. Ṣugbọn ara yá awọn ọta mi, ara wọn le; awọn ti o korira mi lodi npọ̀ si i.

20. Awọn ti o si nfi buburu san rere li ọta mi; nitori emi ntọpa ohun ti iṣe rere.

21. Oluwa, máṣe kọ̀ mi silẹ; Ọlọrun mi, máṣe jina si mi.

22. Yara lati ran mi lọwọ, Oluwa igbala mi.

Ka pipe ipin O. Daf 38