Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 37:12-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Enia buburu di rikiṣi si olõtọ, o si pa ehin rẹ̀ keke si i lara.

13. Oluwa yio rẹrin rẹ̀; nitori ti o ri pe, ọjọ rẹ̀ mbọ̀.

14. Awọn enia buburu ti fà idà yọ, nwọn si ti fà ọrun wọn le, lati sọ talaka ati alaini kalẹ, ati lati pa iru awọn ti nrin li ọ̀na titọ.

15. Idà wọn yio wọ̀ aiya wọn lọ, ọrun wọn yio si ṣẹ́.

16. Ohun diẹ ti olododo ni sanju ọrọ̀ ọ̀pọ enia buburu.

17. Nitoriti a o ṣẹ́ apa awọn enia buburu: ṣugbọn Oluwa di olododo mu.

18. Oluwa mọ̀ ọjọ ẹni iduro-ṣinṣin: ati ilẹ-ini wọn yio wà lailai.

19. Oju kì yio tì wọn ni igba ibi: ati li ọjọ ìyan a o tẹ́ wọn lọrun.

20. Ṣugbọn awọn enia buburu yio ṣegbe, awọn ọta Oluwa yio dabi ẹwà oko-tutu: nwọn o run; ẹ̃fin ni nwọn o run si.

21. Awọn enia buburu wín, nwọn kò si pada san: ṣugbọn olododo a ma ṣãnu, a si ma fi funni.

22. Nitoriti awọn ẹni-ibukún rẹ̀ ni yio jogun aiye; awọn ẹni-egún rẹ̀ li a o ke kuro.

23. A ṣe ìlana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá: o si ṣe inu didùn si ọ̀na rẹ̀.

24. Bi o tilẹ ṣubu, a kì yio ta a nù kuro patapata; nitoriti Oluwa di ọwọ rẹ̀ mu.

25. Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ̀ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o ma ṣagbe onjẹ.

26. Alãnu li on nigbagbogbo, a ma wín ni: a si ma busi i fun iru-ọmọ rẹ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 37