Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 37:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

2. Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù.

3. Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ.

4. Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ.

5. Fi ọ̀na rẹ̀ le Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ.

6. Yio si mu ododo rẹ jade bi imọlẹ, ati idajọ rẹ bi ọsángangan.

7. Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ.

8. Dakẹ inu-bibi, ki o si kọ̀ ikannu silẹ: máṣe ikanra, ki o má ba ṣe buburu pẹlu.

9. Nitori ti a o ke awọn oluṣe-buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yio jogun aiye.

10. Nitori pe nigba diẹ, awọn enia buburu kì yio si: nitotọ iwọ o fi ara balẹ wò ipò rẹ̀, kì yio si si.

11. Ṣugbọn awọn ọlọkàn-tutù ni yio jogun aiye; nwọn o si ma ṣe inu didùn ninu ọ̀pọlọpọ alafia.

12. Enia buburu di rikiṣi si olõtọ, o si pa ehin rẹ̀ keke si i lara.

13. Oluwa yio rẹrin rẹ̀; nitori ti o ri pe, ọjọ rẹ̀ mbọ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 37