Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 33:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O gbá awọn omi okun jọ bi ẹnipe òkiti kan: o tò ibu jọ ni ile iṣura.

8. Ki gbogbo aiye ki o bẹ̀ru Oluwa: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹ̀ru rẹ̀.

9. Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin.

10. Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki.

11. Imọ Oluwa duro lailai, ìro inu rẹ̀ lati irandiran.

12. Ibukún ni fun orilẹ-ède na, Ọlọrun ẹniti Oluwa iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀.

13. Oluwa wò lati ọrun wá, o ri gbogbo ọmọ enia.

14. Lati ibujoko rẹ̀ o wò gbogbo araiye.

15. O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn.

16. Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọ̀pọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ̀ gba silẹ.

17. Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹ̃ni kì yio fi agbara nla rẹ̀ gbàni silẹ.

18. Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀;

19. Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan.

20. Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa.

Ka pipe ipin O. Daf 33