Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 33:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn.

16. Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọ̀pọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ̀ gba silẹ.

17. Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹ̃ni kì yio fi agbara nla rẹ̀ gbàni silẹ.

18. Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀;

19. Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan.

20. Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa.

21. Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́.

22. Ki ãnu rẹ, Oluwa, ki o wà lara wa, gẹgẹ bi awa ti nṣe ireti rẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 33