Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 31:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi: gbà mi ninu ododo rẹ.

2. Dẹ eti rẹ silẹ si mi: gbà mi nisisiyi: iwọ ma ṣe apata agbara mi, ile-ãbò lati gba mi si.

3. Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: nitorina nitori orukọ rẹ ma ṣe itọ́ mi, ki o si ma ṣe amọ̀na mi.

4. Yọ mi jade ninu àwọn ti nwọn nà silẹ fun mi ni ìkọkọ: nitori iwọ li ãbo mi.

5. Li ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le: iwọ li o ti rà mi pada, Oluwa Ọlọrun otitọ.

6. Emi ti korira awọn ẹniti nfiyesi eke asan: ṣugbọn emi gbẹkẹle Oluwa.

7. Emi o yọ̀, inu mi yio si dùn ninu ãnu rẹ: nitori ti iwọ ti rò ti iṣẹ́ mi; iwọ ti mọ̀ ọkàn mi ninu ipọnju;

Ka pipe ipin O. Daf 31