Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 30:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi.

2. Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da.

3. Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho.

4. Kọrin si Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́, ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀.

5. Nitoripe, ni iṣẹju kan ni ibinu rẹ̀ ipẹ́, li ojurere rẹ̀ ni ìye gbe wà; bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ̀ mbọ li owurọ.

6. Ati ninu alafia mi, emi ni, ipò mi kì yio pada lailai.

7. Oluwa, nipa oju-rere rẹ, iwọ ti mu òke mi duro ṣinṣin: nigbati iwọ pa oju rẹ mọ́, ẹnu yọ mi.

8. Emi kigbe pè ọ, Oluwa; ati si Oluwa li emi mbẹ̀bẹ gidigidi.

9. Ere kili o wà li ẹ̀jẹ mi, nigbati mo ba lọ sinu ihò? erupẹ ni yio ma yìn ọ bi? on ni yio ma sọ̀rọ otitọ rẹ bi?

10. Gbọ́, Oluwa, ki o si ṣãnu fun mi: Oluwa, iwọ ma ṣe oluranlọwọ mi.

11. Iwọ ti sọ ikãnu mi di ijó fun mi; iwọ ti bọ aṣọ-ọ̀fọ mi kuro, iwọ si fi ayọ̀ dì mi li àmure.

Ka pipe ipin O. Daf 30