1. Ẹ FI fun Oluwa, ẹnyin ọmọ awọn alagbara, ẹ fi ogo ati agbara fun Oluwa.
2. Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́.
3. Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀.
4. Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla.
5. Ohùn Oluwa nfà igi kedari ya; lõtọ, Oluwa nfà igi kedari Lebanoni ya.