Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 28:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ, Oluwa, apata mi li emi o kigbe pè, máṣe dakẹ si mi; bi iwọ ba dakẹ si mi, emi o dabi awọn ti o lọ sinu ihò.

2. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi, nigbati mo ba nkigbe pè ọ, nigbati mo ba gbé ọwọ mi soke siha ibi-mimọ́ jùlọ rẹ.

3. Máṣe fà mi lọ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ti nsọ̀rọ alafia si aladugbo wọn, ṣugbọn ìwa-ìka mbẹ̀ li ọkàn wọn.

4. Fi fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, ati gẹgẹ bi ìwa buburu ete wọn, fi fun wọn nipa iṣẹ ọwọ wọn, fi ère wọn fun wọn.

5. Nitori ti nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, tabi iṣẹ ọwọ rẹ̀; on o run wọn, kì yio si gbé wọn ró.

6. Olubukún ni Oluwa, nitoriti o ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi.

7. Oluwa li agbara ati asà mi; on li aiya mi gbẹkẹle, a si nràn mi lọwọ: nitorina inu mi dùn jọjọ: emi o si ma fi orin mi yìn i.

8. Oluwa li agbara wọn, on si li agbara igbala ẹni-ororo rẹ̀.

9. Gbà awọn enia rẹ là, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: ma bọ́ wọn pẹlu, ki o si ma gbé wọn leke lailai.

Ka pipe ipin O. Daf 28