Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 24:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Tani yio gùn ori oke Oluwa lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ́ rẹ̀?

4. Ẹniti o li ọwọ mimọ́, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti kò si bura ẹ̀tan.

5. On ni yio ri ibukún gbà lọwọ Oluwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun igbala rẹ̀.

6. Eyi ni iran awọn ti nṣe afẹri rẹ̀, ti nṣe afẹri rẹ, Ọlọrun Jakobu.

7. Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa.

8. Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara, Oluwa ti o lagbara li ogun.

9. Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ani ki ẹ gbé wọn soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa.

10. Tali Ọba ogo yi? Oluwa awọn ọmọ-ogun; on na li Ọba ogo.

Ka pipe ipin O. Daf 24