Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 23:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini.

2. O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọ́rọ́.

3. O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀.

4. Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu.

Ka pipe ipin O. Daf 23