Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 20:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KI Oluwa ki o gbohùn rẹ li ọjọ ipọnju; orukọ Ọlọrun Jakobu ki o dàbobo ọ.

2. Ki o rán iranlọwọ si ọ lati ibi-mimọ́ wá, ki o si tì ọ lẹhin lati Sioni wá.

3. Ki o ranti ẹbọ-ọrẹ rẹ gbogbo, ki o si gbà ẹbọ sisun rẹ.

4. Ki o fi fun ọ gẹgẹ bi ti inu rẹ, ki o si mu gbogbo ìmọ rẹ ṣẹ.

5. Awa o ma kọrin ayọ̀ igbala rẹ, ati li orukọ Ọlọrun wa li awa o fi ọpágun wa de ilẹ; ki Oluwa ki o mu gbogbo ibère rẹ ṣẹ.

6. Nigbayi ni mo to mọ̀ pe Oluwa gbà Ẹni-ororo rẹ̀ là; yio gbọ́ ọ lati ọrun mimọ́ rẹ̀ wá nipa agbara igbala ọwọ ọ̀tun rẹ̀.

7. Awọn ẹlomiran gbẹkẹle kẹkẹ́, awọn ẹlomiran le ẹṣin; ṣugbọn awa o ranti orukọ Oluwa Ọlọrun wa.

8. Nwọn wolẹ, nwọn si ṣubu: ṣugbọn awa dide awa si duro ṣinṣin.

Ka pipe ipin O. Daf 20