Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 18:8-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ẹ̃fin ti iho imu rẹ̀ jade, ati iná lati ẹnu rẹ̀ wá njonirun: ẹyín gbiná nipasẹ rẹ̀.

9. O tẹri ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ wá: òkunkun si mbẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀.

10. O si gùn ori kerubu o si fò: nitõtọ, o nra lori iyẹ-apa afẹ́fẹ́.

11. O fi òkunkun ṣe ibi ìkọkọ rẹ̀: ani agọ́ rẹ̀ yi i ka kiri; omi dudu, ati awọsanma oju-ọrun ṣiṣu dudu.

12. Nipa imọlẹ iwaju rẹ̀, awọsanma ṣiṣu dùdu rẹ̀ kọja lọ, yinyín ati ẹyín iná.

13. Oluwa sán ãra pẹlu li ọrun, Ọga-ogo si fọ̀ ohùn rẹ̀: yinyín ati ẹyín iná!

14. Lõtọ, o rán ọfa rẹ̀ jade, o si tú wọn ká: ọ̀pọlọpọ manamana li o si fi ṣẹ́ wọn tũtu.

15. Nigbana li awowò omi odò hàn, a si ri ipilẹ aiye nipa ibawi rẹ, Oluwa, nipa fifun ẽmi iho imu rẹ.

16. O ranṣẹ́ lati òke wá, o mu mi, o fà mi jade wá lati inu omi nla.

17. O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, ati lọwọ awọn ti o korira mi; nitori nwọn li agbara jù mi lọ.

18. Nwọn dojukọ mi li ọjọ ipọnju mi: ṣugbọn Oluwa li alafẹhintì mi.

19. O mu mi jade pẹlu sinu ibi nla; o gbà mi nitori inu rẹ̀ dùn si mi.

20. Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi; gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li o san a fun mi.

21. Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi.

22. Nitori pe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi, bẹ̃li emi kò si yẹ̀ ofin rẹ̀ kuro lọdọ mi.

23. Emi si duro ṣinṣin pẹlu rẹ̀, emi si paramọ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi.

24. Nitorina li Oluwa ṣe san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li oju rẹ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 18