Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 18:34-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ.

35. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla.

36. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀.

37. Emi ti le awọn ọta mi, emi si bá wọn: bẹ̃li emi kò pada sẹhin titi a fi run wọn.

38. Emi ṣá wọn li ọgbẹ ti nwọn kò fi le dide, nwọn ṣubu li abẹ ẹsẹ mi.

39. Nitoriti iwọ fi agbara di mi li àmure si ogun na: iwọ ti mu awọn ti o dide si mi tẹriba li abẹ ẹsẹ mi.

40. Iwọ si yi ẹhin awọn ọta mi pada fun mi pẹlu; emi si pa awọn ti o korira mi run.

41. Nwọn kigbe, ṣugbọn kò si ẹniti o gbà wọn; ani si Oluwa, ṣugbọn kò dá wọn li ohùn.

42. Nigbana ni mo gún wọn kunna bi ekuru niwaju afẹfẹ: mo kó wọn jade bi ohun ẹ̀gbin ni ita.

43. Iwọ ti yọ mi kuro ninu ìja awọn enia; iwọ fi mi jẹ olori awọn orilẹ-ède: enia ti emi kò ti mọ̀, yio si ma sìn mi.

44. Bi nwọn ti gburo mi, nwọn o gbà mi gbọ́: awọn ọmọ àjeji yio fi ẹ̀tan tẹ̀ ori wọn ba fun mi.

45. Aiya yio pá awọn alejo, nwọn o si fi ibẹ̀ru jade ni ibi kọlọfin wọn.

46. Oluwa mbẹ; olubukún si li apáta mi; ki a si gbé Ọlọrun igbala mi leke.

Ka pipe ipin O. Daf 18