Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 18:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi.

2. Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi.

3. Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.

4. Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi.

5. Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu.

6. Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀.

7. Nigbana ni ilẹ mì, o si wariri: ipilẹ òke pẹlu ṣidi, o si mì, nitoriti o binu.

8. Ẹ̃fin ti iho imu rẹ̀ jade, ati iná lati ẹnu rẹ̀ wá njonirun: ẹyín gbiná nipasẹ rẹ̀.

9. O tẹri ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ wá: òkunkun si mbẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀.

10. O si gùn ori kerubu o si fò: nitõtọ, o nra lori iyẹ-apa afẹ́fẹ́.

11. O fi òkunkun ṣe ibi ìkọkọ rẹ̀: ani agọ́ rẹ̀ yi i ka kiri; omi dudu, ati awọsanma oju-ọrun ṣiṣu dudu.

Ka pipe ipin O. Daf 18