Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 16:4-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi.

5. Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro.

6. Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere.

7. Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru.

8. Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò.

9. Nitorina ni inu mi ṣe dùn, ti ogo mi si nyọ̀; ara mi pẹlu yio simi ni ireti.

10. Nitori iwọ kì yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bẹ̃ni iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ.

11. Iwọ o fi ipa ọ̀na ìye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ̀ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai.

Ka pipe ipin O. Daf 16