Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 16:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, pa mi mọ́: nitori iwọ ni mo gbẹkẹ mi le.

2. Ọkàn mi, iwọ ti wi fun Oluwa pe, Iwọ li Oluwa mi: emi kò ni ire kan lẹhin rẹ.

3. Si awọn enia mimọ́ ti o wà li aiye, ani si awọn ọlọla, lara ẹniti didùn inu mi gbogbo gbe wà.

4. Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi.

5. Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro.

6. Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere.

7. Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru.

8. Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò.

Ka pipe ipin O. Daf 16