Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 148:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga.

2. Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀.

3. Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ.

4. Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun.

5. Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn.

6. O si fi idi wọn mulẹ lai ati lailai; o si ti ṣe ilana kan ti kì yio kọja.

7. Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi, ati gbogbo ibu-omi;

8. Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;

9. Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso, ati gbogbo igi Kedari;

10. Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin; ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò;

11. Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia; ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye;

Ka pipe ipin O. Daf 148