Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 146:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Fi iyìn fun Oluwa, iwọ ọkàn mi.

2. Nigbati mo wà lãye li emi o ma fi iyìn fun Oluwa: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi, nigbati mo wà.

3. Ẹ máṣe gbẹkẹ nyin le awọn ọmọ-alade, ani le ọmọ-enia, lọwọ ẹniti kò si iranlọwọ.

4. Ẹmi rẹ̀ jade lọ, o pada si erupẹ rẹ̀; li ọjọ na gan, ìro inu rẹ̀ run.

5. Ibukún ni fun ẹniti o ni Ọlọrun Jakobu fun iranlọwọ rẹ̀, ireti ẹniti mbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀:

6. Ẹniti o da ọrun on aiye, okun ati ohun ti o wà ninu wọn: ẹniti o pa otitọ mọ́ titi aiye:

7. Ẹniti o nṣe idajọ fun ẹni-inilara: ẹniti o nfi onjẹ fun ẹniti ebi npa. Oluwa tú awọn aratubu silẹ:

8. Oluwa ṣi oju awọn afọju: Oluwa gbé awọn ti a tẹ̀ lori ba dide; Oluwa fẹ awọn olododo:

9. Oluwa pa awọn alejo mọ́; o tù awọn alainibaba ati opo lara: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio darú.

10. Oluwa yio jọba lailai, ani Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni, lati iran-diran gbogbo. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Ka pipe ipin O. Daf 146