Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 144:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUBUKÚN li oluwa apata mi, ẹniti o kọ́ ọwọ mi li ogun, ati ika mi ni ìja:

2. Õre mi, ati odi-agbara mi; ile-iṣọ giga, ati olugbala mi; asà mi, ati ẹniti mo gbẹkẹle; eniti o tẹri awọn enia mi ba labẹ mi.

3. Oluwa, kili enia, ti iwọ fi nkiye si i! tabi ọmọ enia, ti iwọ fi nronú rẹ̀!

4. Enia dabi asan: bi ojìji ti nkọja lọ li ọjọ rẹ̀.

5. Oluwa, tẹ̀ ọrun rẹ ba, ki o si sọ̀kalẹ: tọ́ awọn òke nla, nwọn o si ru ẽfin.

6. Kọ manamana jade, ki o si tú wọn ka: ta ọfà rẹ ki o si dà wọn rú.

7. Rán ọwọ rẹ lati òke wá; yọ mi, ki o si gbà mi kuro ninu omi nla, li ọwọ awọn ọmọ àjeji.

8. Ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ọwọ ọtún wọn si jẹ ọwọ ọtún eke.

9. Ọlọrun, emi o kọ orin titun si ọ: lara ohun ọnà orin olokùn mẹwa li emi o kọrin iyìn si ọ.

10. On li o nfi igbala fun awọn ọba: ẹniti o gbà Dafidi iranṣẹ rẹ̀ lọwọ idà ipanilara.

11. Yọ mi, ki o si gbà mi lọwọ awọn ọmọ àjeji, ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ati ọwọ ọtún wọn jẹ ọwọ ọtún eke:

12. Ki awọn ọmọkunrin wa, ki o dabi igi gbigbin ti o dagba ni igba-ewe wọn; ki awọn ọmọbinrin wa ki o le dabi ọwọ̀n igun-ile, ti a ṣe lọnà bi afarawe ãfin.

Ka pipe ipin O. Daf 144