Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 143:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, gbọ́ adura mi, fi eti si ẹ̀bẹ mi; ninu otitọ rẹ dá mi lohùn ati ninu ododo rẹ.

2. Ki o má si ba ọmọ-ọdọ rẹ lọ sinu idajọ, nitori ti kò si ẹniti o wà lãye ti a o dalare niwaju rẹ.

3. Nitori ti ọta ti ṣe inunibini si ọkàn mi; o ti lù ẹmi mi bolẹ; o ti mu mi joko li òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.

4. Nitorina li ẹmi mi ṣe rẹ̀wẹsi ninu mi; òfo fò aiya mi ninu mi.

5. Emi ranti ọjọ atijọ; emi ṣe àṣaro iṣẹ rẹ gbogbo, emi nronu iṣẹ ọwọ rẹ.

6. Emi nà ọwọ mi si ọ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi bi ilẹ gbigbẹ.

7. Oluwa, gbọ́ temi nisisiyi; o rẹ̀ ọkàn mi tan; máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi, ki emi ki o má bà dabi awọn ti o lọ sinu ihò.

8. Mu mi gbọ́ iṣeun-ifẹ rẹ li owurọ; nitori iwọ ni mo gbẹkẹle: mu mi mọ̀ ọ̀na ti emi iba ma tọ̀; nitori mo gbé ọkàn mi soke si ọ.

Ka pipe ipin O. Daf 143