Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 142:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA ni mo fi ohùn mi kigbe pè; ohùn mi ni mo fi mbẹ̀bẹ mi si Oluwa.

2. Emi tú aroye mi silẹ niwaju rẹ̀; emi fi iṣẹ́ mi hàn niwaju rẹ̀.

3. Nigbati ọkàn mi rẹ̀wẹsi ninu mi, nigbana ni iwọ mọ̀ ipa-ọ̀na mi. Li ọ̀na ti emi nrìn ni nwọn dẹkùn silẹ fun mi nikọ̀kọ.

4. Emi wò ọwọ ọtún, mo si ri pe, kò si ẹnikan ti o mọ̀ mi: àbo dẹti fun mi; kò si ẹniti o nãni ọkàn mi.

5. Oluwa, iwọ ni mo kigbe pè: emi wipe, iwọ li àbo mi ati ipin mi ni ilẹ alãye.

6. Fiyesi igbe mi: nitori ti a rẹ̀ mi silẹ gidigidi: gbà mi lọwọ awọn oninu-nibini mi. Nitori nwọn lagbara ju mi lọ.

Ka pipe ipin O. Daf 142