Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 141:6-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nigbati a ba bì awọn onidajọ wọn ṣubu ni ibi okuta, nwọn o gbọ́ ọ̀rọ mi, nitori ti o dùn.

7. Egungun wa tàn kalẹ li ẹnu isà-òkú, ẹniti o la aporo sori ilẹ.

8. Ṣugbọn oju mi mbẹ lara rẹ; Ọlọrun Oluwa, lọdọ rẹ ni igbẹkẹle mi wà; máṣe tú ọkàn mi dà silẹ.

9. Pa mi mọ́ kuro ninu okùn ti nwọn dẹ silẹ fun mi, ati ikẹkùn awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

10. Jẹ ki awọn enia buburu ki o bọ́ sinu àwọn ara wọn, nigbati emi ba kọja lọ.

Ka pipe ipin O. Daf 141