Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 140:2-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹniti nrò ìwa-buburu ni inu wọn; nigbagbogbo ni nwọn nrú ìja soke si mi.

3. Nwọn ti pọ́n ahọn wọn bi ejo; oro pãmọlẹ mbẹ li abẹ ète wọn.

4. Oluwa, pa mi mọ́ kuro lọwọ enia buburu; yọ mi kuro lọwọ ọkunrin ìka nì; ẹniti o ti pinnu rẹ̀ lati bì ìrin mi ṣubu.

5. Awọn agberaga dẹ pakute silẹ fun mi, ati okùn; nwọn ti nà àwọn lẹba ọ̀na; nwọn ti kẹkùn silẹ fun mi.

6. Emi wi fun Oluwa pe, iwọ li Ọlọrun mi: Oluwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi.

7. Ọlọrun Oluwa, agbara igbala mi, iwọ li o bò ori mi mọlẹ li ọjọ ìja.

Ka pipe ipin O. Daf 140