Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 14:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ, nwọn si nṣe iṣẹ irira, kò si ẹniti nṣe rere.

2. Oluwa bojuwò lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun.

3. Gbogbo wọn li o si jumọ yà si apakan, nwọn si di elẽri patapata; kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan.

4. Gbogbo awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ kò ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun, nwọn kò si kepè Oluwa.

5. Nibẹ ni ẹ̀ru bà wọn gidigidi: nitoriti Ọlọrun mbẹ ninu iran olododo.

6. Ẹnyin dojutì ìmọ awọn talaka, ṣugbọn Oluwa li àbo rẹ̀.

7. Tani yio fi igbala fun Israeli lati Sioni jade wá! nigbati Oluwa ba mu ikólọ awọn enia rẹ̀ pada bọ̀, Jakobu yio yọ̀, inu Israeli yio si dùn.

Ka pipe ipin O. Daf 14