Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 139:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi.

14. Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju.

15. Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye.

16. Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi.

17. Ọlọrun, ìro inu rẹ ti ṣe iye-biye to fun mi, iye wọn ti pọ̀ to!

18. Emi iba kà wọn, nwọn jù iyanrin lọ ni iye: nigbati mo ba jí, emi wà lọdọ rẹ sibẹ.

19. Ọlọrun iba jẹ pa enia buburu nitõtọ: nitorina kuro lọdọ mi ẹnyin ọkunrin ẹ̀jẹ.

20. Ẹniti nfi inu buburu sọ̀rọ si ọ, awọn ọta rẹ npè orukọ rẹ li asan!

21. Oluwa, njẹ emi kò korira awọn ti o korira rẹ? njẹ inu mi kò ha si bajẹ si awọn ti o dide si ọ?

22. Emi korira wọn li àkotan: emi kà wọn si ọta mi.

23. Ọlọrun, wadi mi, ki o si mọ̀ aiya mi: dán mi wò, ki o si mọ̀ ìro-inu mi:

24. Ki o si wò bi ipa-ọ̀na buburu kan ba wà ninu mi, ki o si fi ẹsẹ mi le ọ̀na ainipẹkun.

Ka pipe ipin O. Daf 139