Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 138:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI o ma yìn ọ tinu-tinu mi gbogbo; niwaju awọn oriṣa li emi o ma kọrin iyìn si ọ.

2. Emi o ma gbadura siha tempili mimọ́ rẹ, emi o si ma yìn orukọ rẹ nitori iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ; nitori iwọ gbé ọ̀rọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ.

3. Li ọjọ ti mo kepè, iwọ da mi lohùn, iwọ si fi ipa mu mi lara le li ọkàn mi.

4. Gbogbo awọn ọba aiye yio yìn ọ, Oluwa, nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ.

5. Nitõtọ, nwọn o ma kọrin ni ipa-ọ̀na Oluwa: nitori pe nla li ogo Oluwa.

6. Bi Oluwa tilẹ ga, sibẹ o juba awọn onirẹlẹ; ṣugbọn agberaga li o mọ̀ li òkere rére.

7. Bi emi tilẹ nrìn ninu ipọnju, iwọ ni yio sọ mi di ãye: iwọ o nà ọwọ rẹ si ibinu awọn ọta mi, ọwọ ọtún rẹ yio si gbà mi.

8. Oluwa yio ṣe ohun ti iṣe ti emi li aṣepe: Oluwa, ãnu rẹ duro lailai: máṣe kọ̀ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 138