Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 137:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ẹba odò Babeli, nibẹ li awa gbe joko, awa si sọkun nigbati awa ranti Sioni.

2. Awa fi duru wa kọ́ si ori igi wíllo ti o wà lãrin rẹ̀.

3. Nitoripe nibẹ li awọn ti o kó wa ni igbekun bère orin lọwọ wa; ati awọn ti o ni wa lara bère idaraya wipe; Ẹ kọ orin Sioni kan fun wa.

4. Awa o ti ṣe kọ orin Oluwa ni ilẹ àjeji?

5. Jerusalemu, bi emi ba gbagbe rẹ, jẹ ki ọwọ ọtún mi ki o gbagbe ìlò rẹ̀.

6. Bi emi kò ba ranti rẹ, jẹ ki ahọn mi ki o lẹ̀ mọ èrìgì mi; bi emi kò ba fi Jerusalemu ṣaju olori ayọ̀ mi gbogbo.

7. Oluwa, ranti ọjọ Jerusalemu lara awọn ọmọ Edomu, awọn ẹniti nwipe, Wó o palẹ, wó o palẹ, de ipilẹ rẹ̀!

8. Iwọ, ọmọbinrin Babeli, ẹniti a o parun; ibukún ni fun ẹniti o san a fun ọ bi iwọ ti hù si wa.

9. Ibukún li ẹniti o mu, ti o si fi ọmọ wẹwẹ rẹ ṣán okuta.

Ka pipe ipin O. Daf 137