Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 135:6-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo.

7. O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá.

8. Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko.

9. Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo.

10. Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba.

11. Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani:

12. O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀.

13. Oluwa, orukọ rẹ duro lailai; iranti rẹ Oluwa, lati iran-diran.

14. Nitori ti Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si ṣe iyọ́nu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀,

15. Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia.

16. Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran.

17. Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn.

18. Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.

19. Ẹnyin arale Israeli, ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin arale Aaroni, ẹ fi ibukún fun Oluwa.

Ka pipe ipin O. Daf 135