Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 135:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ yìn Oluwa, Ẹ yìn orukọ Oluwa; ẹ yìn i, ẹnyin iranṣẹ Oluwa.

2. Ẹnyin ti nduro ni ile Oluwa, ninu agbalá ile Ọlọrun wa.

3. Ẹ yìn Oluwa: nitori ti Oluwa ṣeun; ẹ kọrin iyìn si orukọ rẹ̀; ni orin ti o dùn.

4. Nitori ti Oluwa ti yàn Jakobu fun ara rẹ̀; ani Israeli fun iṣura ãyo rẹ̀.

5. Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ.

6. Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo.

7. O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá.

8. Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko.

9. Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo.

10. Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba.

Ka pipe ipin O. Daf 135