Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 127:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan.

2. Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun.

3. Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀.

4. Bi ọfà ti ri li ọwọ alagbara, bẹ̃li awọn ọmọ igbà èwe rẹ.

5. Ibukún ni fun ọkunrin na ti apo rẹ̀ kún fun wọn: oju kì yio tì wọn, ṣugbọn nwọn o ṣẹgun awọn ọta li ẹnu ọ̀na.

Ka pipe ipin O. Daf 127