Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 125:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ti o gbẹkẹle Oluwa yio dabi òke Sioni, ti a kò le ṣi ni idi, bikoṣepe o duro lailai.

2. Bi òke nla ti yi Jerusalemu ka, bẹ̃li Oluwa yi awọn enia rẹ̀ ka lati isisiyi lọ ati titi lailai.

3. Nitori ti ọpá awọn enia buburu kì yio bà le ipin awọn olododo: ki awọn olododo ki o má ba fi ọwọ wọn le ẹ̀ṣẹ.

4. Oluwa ṣe rere fun awọn ẹni-rere, ati fun awọn ti aiya wọn duro ṣinṣin.

5. Bi o ṣe ti iru awọn ti nwọn yà si ipa ọ̀na wiwọ wọn: Oluwa yio jẹ ki wọn lọ pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn alafia yio wà lori Israeli.

Ka pipe ipin O. Daf 125