Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 124:2-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Iba máṣe pe Oluwa ti o ti wà fun wa, nigbati awọn enia duro si wa:

3. Nigbana ni nwọn iba gbé wa mì lãye, nigbati ibinu nwọn ru si wa:

4. Nigbana li omi wọnni iba bò wa mọlẹ, iṣan omi iba ti bori ọkàn wa:

5. Nigbana li agberaga omi iba bori ọkàn wa.

6. Olubukún li Oluwa, ti kò fi wa fun wọn bi ohun ọdẹ fun ehin wọn.

7. Ọkàn wa yọ bi ẹiyẹ jade kuro ninu okùn apẹiyẹ: okùn já, awa si yọ.

8. Iranlọwọ wa mbẹ li orukọ Oluwa, ti o da ọrun on aiye.

Ka pipe ipin O. Daf 124