Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 12:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBÀ-NI Oluwa; nitori awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun dasẹ̀; nitori awọn olõtọ dasẹ̀ kuro ninu awọn ọmọ enia.

2. Olukuluku wọn mba ẹnikeji rẹ̀ sọ asan; ète ipọnni ati ọkàn meji ni nwọn fi nsọ.

3. Oluwa yio ké gbogbo ète ipọnni kuro, ati ahọn ti nsọ̀rọ ohun nla.

4. Ti o wipe, Ahọn wa li awa o fi ṣẹgun; ète wa ni ti wa: tani iṣe oluwa wa?

5. Nitori inira awọn talaka, nitori imi-ẹ̀dun awọn alaini, Oluwa wipe, nigbayi li emi o dide; emi o si yọ ọ si ibi ailewu kuro lọwọ ẹniti nfẹ̀ si i.

6. Ọ̀rọ Oluwa, ọ̀rọ funfun ni, bi fadaka ti a yọ́ ni ileru erupẹ, ti a dà ni igba meje.

7. Iwọ o pa wọn mọ́, Oluwa, iwọ o pa olukuluku wọn mọ́ kuro lọwọ iran yi lailai.

8. Awọn enia buburu nrìn ni iha gbogbo, nigbati a ba gbé awọn enia-kenia leke.

Ka pipe ipin O. Daf 12