Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!

6. Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.

7. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ.

8. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.

9. Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

10. Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ.

11. Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.

12. Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ.

13. Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ.

14. Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 119