Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:47-56 Yorùbá Bibeli (YCE)

47. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ.

48. Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ.

49. Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti.

50. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye.

51. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ.

52. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu.

53. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ.

54. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi.

55. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́.

56. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́.

Ka pipe ipin O. Daf 119