Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:41-56 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

42. Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ.

43. Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ.

44. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai.

45. Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ.

46. Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju.

47. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ.

48. Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ.

49. Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti.

50. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye.

51. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ.

52. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu.

53. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ.

54. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi.

55. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́.

56. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́.

Ka pipe ipin O. Daf 119