Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:36-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro.

37. Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ.

38. Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀.

39. Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara.

40. Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ.

41. Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

42. Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ.

43. Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ.

44. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai.

Ka pipe ipin O. Daf 119