Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:25-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

26. Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ.

27. Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ.

28. Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

29. Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi.

30. Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi.

31. Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi.

32. Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye.

33. Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin.

34. Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo.

35. Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi.

36. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro.

Ka pipe ipin O. Daf 119