Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:161-176 Yorùbá Bibeli (YCE)

161. Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ.

162. Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ.

163. Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ.

164. Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ.

165. Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn.

166. Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ.

167. Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi.

168. Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ.

169. Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

170. Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

171. Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ.

172. Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ.

173. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ.

174. Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi.

175. Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ.

176. Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 119