Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:155-167 Yorùbá Bibeli (YCE)

155. Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ.

156. Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ.

157. Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ.

158. Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

159. Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ.

160. Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai.

161. Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ.

162. Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ.

163. Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ.

164. Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ.

165. Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn.

166. Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ.

167. Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi.

Ka pipe ipin O. Daf 119