Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:136-147 Yorùbá Bibeli (YCE)

136. Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́.

137. Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ.

138. Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi.

139. Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ.

140. Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ.

141. Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ.

142. Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ.

143. Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi.

144. Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè.

145. Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́.

146. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́.

147. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 119