Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:118-129 Yorùbá Bibeli (YCE)

118. Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn.

119. Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ.

120. Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ.

121. Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi.

122. Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara.

123. Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ.

124. Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ.

125. Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ.

126. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo.

127. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ.

128. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.

129. Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́.

Ka pipe ipin O. Daf 119