Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 119:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa.

2. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo.

3. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀.

4. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi.

5. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!

6. Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.

7. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ.

8. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.

Ka pipe ipin O. Daf 119