Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 116:6-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ.

7. Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ.

8. Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu.

9. Emi o ma rìn niwaju Oluwa ni ilẹ alãye.

10. Emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: mo ri ipọnju gidigidi.

11. Mo wi ni iyara mi pe: Eke ni gbogbo enia.

12. Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore rẹ̀ si mi?

13. Emi o mu ago igbala, emi o si ma kepè orukọ Oluwa.

14. Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.

15. Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ̀ li oju Oluwa.

16. Oluwa nitõtọ iranṣẹ rẹ li emi; iranṣẹ rẹ̀ li emi, ati ọmọ iranṣẹ-birin rẹ: iwọ ti tú ìde mi.

17. Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o ma ke pè orukọ Oluwa.

Ka pipe ipin O. Daf 116