Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 116:15-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ̀ li oju Oluwa.

16. Oluwa nitõtọ iranṣẹ rẹ li emi; iranṣẹ rẹ̀ li emi, ati ọmọ iranṣẹ-birin rẹ: iwọ ti tú ìde mi.

17. Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o ma ke pè orukọ Oluwa.

18. Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.

19. Ninu àgbala ile Oluwa, li arin rẹ, iwọ Jerusalemu. Ẹ yìn Oluwa.

Ka pipe ipin O. Daf 116